3 nígbà náà, Jèhófà Ọlọ́run rẹ máa mú àwọn èèyàn rẹ tí wọ́n kó lẹ́rú+ pa dà wá, ó máa ṣàánú+ rẹ, ó sì máa kó ọ jọ látọ̀dọ̀ gbogbo èèyàn tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ tú ọ+ ká sí.
2Àwọn yìí ni àwọn èèyàn ìpínlẹ̀,* tí wọ́n pa dà lára àwọn tó wà nígbèkùn,+ àwọn tí Nebukadinésárì ọba Bábílónì kó lọ sí ìgbèkùn ní Bábílónì,+ àmọ́ tí wọ́n pa dà sí Jerúsálẹ́mù àti Júdà nígbà tó yá, kálukú pa dà sí ìlú rẹ̀,+
6 Ojú mi yóò wà lára wọn láti ṣe wọ́n lóore, màá sì mú kí wọ́n pa dà sí ilẹ̀ yìí.+ Màá gbé wọn ró, mi ò sì ní ya wọ́n lulẹ̀, màá gbìn wọ́n, mi ò sì ní fà wọ́n tu.+