-
Ìsíkíẹ́lì 34:11-13Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
11 “‘Torí ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Wò ó, èmi fúnra mi yóò wá àwọn àgùntàn mi, màá sì bójú tó wọn.+ 12 Èmi yóò bójú tó àwọn àgùntàn mi bí olùṣọ́ àgùntàn tó rí àwọn àgùntàn rẹ̀ tó fọ́n ká, tó sì ń fún wọn ní oúnjẹ.+ Èmi yóò gbà wọ́n sílẹ̀ kúrò ní gbogbo ibi tí wọ́n fọ́n ká sí ní ọjọ́ ìkùukùu* àti ìṣúdùdù tó kàmàmà.+ 13 Èmi yóò mú wọn jáde láàárín àwọn èèyàn, màá sì kó wọn jọ láti àwọn ilẹ̀. Èmi yóò mú wọn wá sórí ilẹ̀ wọn, màá sì bọ́ wọn lórí àwọn òkè Ísírẹ́lì,+ lẹ́gbẹ̀ẹ́ omi tó ń ṣàn àti lẹ́gbẹ̀ẹ́ gbogbo ibi tí wọ́n ń gbé ní ilẹ̀ náà.
-