21 ‘Sọ fún ilé Ísírẹ́lì pé: “Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí, ‘Mo máa tó sọ ibi mímọ́ mi di aláìmọ́,+ ibi pàtàkì tí ẹ fi ń yangàn, tí ẹ fẹ́ràn gidigidi, tó sì máa ń wù yín.* Idà ni wọn yóò fi pa àwọn ọmọ yín ọkùnrin àti obìnrin tí ẹ fi sílẹ̀.+