25 Jèhófà máa mú kí àwọn ọ̀tá+ rẹ ṣẹ́gun rẹ. Ọ̀nà kan lo máa gbà yọ sí wọn láti bá wọn jà, àmọ́ ọ̀nà méje ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lo máa gbà sá kúrò lọ́dọ̀ wọn; o sì máa di ohun àríbẹ̀rù fún gbogbo ìjọba+ ayé.
65 Ọkàn rẹ ò ní balẹ̀ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè+ yẹn, àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ ò sì ní rí ibi ìsinmi. Dípò ìyẹn, Jèhófà máa mú kí o kó ọkàn sókè,+ ojú rẹ á di bàìbàì, ìrẹ̀wẹ̀sì*+ á sì bá ọ níbẹ̀.