-
2 Àwọn Ọba 24:14, 15Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
14 Ó kó gbogbo Jerúsálẹ́mù lọ sí ìgbèkùn, gbogbo ìjòyè,+ gbogbo jagunjagun tó lákíkanjú àti gbogbo oníṣẹ́ ọnà pẹ̀lú gbogbo oníṣẹ́ irin,*+ ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) èèyàn ló kó lọ sí ìgbèkùn. Kò ṣẹ́ ku ẹnì kankan àfi àwọn aláìní ní ilẹ̀ náà.+ 15 Bó ṣe mú Jèhóákínì+ lọ sí ìgbèkùn ní Bábílónì+ nìyẹn; ó tún mú ìyá ọba, àwọn ìyàwó ọba, àwọn òṣìṣẹ́ ààfin àti àwọn aṣáájú ilẹ̀ náà, ó sì kó wọn ní ìgbèkùn láti Jerúsálẹ́mù lọ sí Bábílónì.
-
-
Jeremáyà 39:9Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
9 Nebusarádánì+ olórí ẹ̀ṣọ́ kó àwọn tó ṣẹ́ kù lára àwọn èèyàn tó wà ní ìlú náà lọ sí ìgbèkùn ní Bábílónì àti àwọn tó sá wá sọ́dọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú ẹnikẹ́ni tí ó ṣẹ́ kù.
-