2 Màá mú kí o di orílẹ̀-èdè ńlá, màá sì bù kún ọ. Màá mú kí orúkọ rẹ di ńlá, ó sì máa jẹ́ ìbùkún.+ 3 Màá súre fún àwọn tó ń súre fún ọ, màá sì gégùn-ún fún ẹni tó bá gégùn-ún fún ọ,+ ó dájú pé gbogbo ìdílé tó wà lórí ilẹ̀ yóò rí ìbùkún gbà nípasẹ̀ rẹ.”+