-
Diutarónómì 30:8-10Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
8 “Nígbà náà, wàá pa dà, wàá fetí sí ohùn Jèhófà, wàá sì pa gbogbo àṣẹ rẹ̀ tí mò ń pa fún ọ lónìí mọ́. 9 Jèhófà Ọlọ́run rẹ máa bù kún gbogbo iṣẹ́ ọwọ́+ rẹ lọ́pọ̀lọpọ̀, ó máa mú kí àwọn ọmọ rẹ, àwọn ẹran ọ̀sìn rẹ àti èso ilẹ̀ rẹ di púpọ̀, torí pé lẹ́ẹ̀kan sí i inú Jèhófà máa dùn láti mú kí nǹkan lọ dáadáa fún ọ bí inú rẹ̀ ṣe dùn sí àwọn baba ńlá+ rẹ. 10 Nígbà yẹn, wàá fetí sí ohùn Jèhófà Ọlọ́run rẹ, wàá sì pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́ àti àwọn òfin rẹ̀ tí wọ́n kọ sínú ìwé Òfin yìí, wàá sì fi gbogbo ọkàn rẹ àti gbogbo ara*+ rẹ pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run rẹ.
-
-
Ìsíkíẹ́lì 36:27Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
27 Èmi yóò fi ẹ̀mí mi sínú yín, màá sì mú kí ẹ máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà mi.+ Ẹ ó máa tẹ̀ lé ìdájọ́ mi, ẹ ó sì máa pa wọ́n mọ́.
-