-
Ìsíkíẹ́lì 38:4-6Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
4 Èmi yóò yí ojú rẹ pa dà, màá fi ìwọ̀ kọ́ ọ lẹ́nu,+ èmi yóò sì mú ìwọ àti gbogbo ọmọ ogun rẹ jáde,+ àwọn ẹṣin àti àwọn tó ń gẹṣin tí gbogbo wọn wọṣọ iyì, ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èèyàn pẹ̀lú àwọn apata ńlá àti asà,* gbogbo wọn ní idà; 5 Páṣíà, Etiópíà àti Pútì+ wà pẹ̀lú wọn, gbogbo wọn ní asà* àti akoto;* 6 Gómérì àti gbogbo ọmọ ogun rẹ̀, ilé Tógámà+ láti ibi tó jìnnà jù ní àríwá, pẹ̀lú gbogbo ọmọ ogun rẹ̀; ọ̀pọ̀ èèyàn wà pẹ̀lú rẹ.+
-
-
Ìfihàn 19:17, 18Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
17 Mo tún rí áńgẹ́lì kan tó dúró sínú oòrùn, ó fi ohùn tó dún ketekete sọ̀rọ̀, ó sọ fún gbogbo ẹyẹ tó ń fò lójú ọ̀run* pé: “Ẹ wá síbí, ẹ kóra jọ síbi oúnjẹ alẹ́ ńlá ti Ọlọ́run,+ 18 kí ẹ lè jẹ ẹran ara àwọn ọba àti ẹran ara àwọn ọ̀gágun àti ẹran ara àwọn ọkùnrin alágbára+ àti ẹran ara àwọn ẹṣin àti ti àwọn tó jókòó sórí wọn+ àti ẹran ara gbogbo èèyàn, ti ẹni tó wà lómìnira àti ti ẹrú, ti àwọn ẹni kékeré àti ẹni ńlá.”
-