ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ẹ́kísódù 7:4
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 4 Àmọ́ Fáráò ò ní fetí sí yín. Ọwọ́ mi yóò tẹ Íjíbítì, màá sì fi ìdájọ́ tó rinlẹ̀ mú ogunlọ́gọ̀ mi,* ìyẹn àwọn èèyàn mi, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde ní ilẹ̀ náà.+

  • Ẹ́kísódù 14:4
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 4 Màá jẹ́ kí ọkàn Fáráò le,+ ó máa lépa wọn, màá sì ṣe ara mi lógo nípasẹ̀ Fáráò àti gbogbo ọmọ ogun rẹ̀.+ Ó dájú pé àwọn ará Íjíbítì yóò mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.”+ Ohun tí wọ́n sì ṣe nìyẹn.

  • Àìsáyà 37:20
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 20 Àmọ́ ní báyìí, ìwọ Jèhófà Ọlọ́run wa, gbà wá lọ́wọ́ rẹ̀, kí gbogbo ìjọba ayé lè mọ̀ pé ìwọ Jèhófà nìkan ṣoṣo ni Ọlọ́run.”+

  • Ìsíkíẹ́lì 38:16
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 16 Ìwọ yóò wá gbéjà ko àwọn èèyàn mi Ísírẹ́lì bí ìgbà tí ìkùukùu* bo ilẹ̀. Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, èmi yóò mú kí o wá gbéjà ko ilẹ̀ mi,+ kí àwọn orílẹ̀-èdè lè mọ̀ mí, kí wọ́n sì mọ̀ pé ẹni mímọ́ ni mí nígbà tí wọ́n bá rí ohun tí mo ṣe sí ọ, ìwọ Gọ́ọ̀gù.”’+

  • Málákì 1:11
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 11 “Torí láti yíyọ oòrùn dé wíwọ̀ rẹ̀,* wọn yóò gbé orúkọ mi ga láàárín àwọn orílẹ̀-èdè.+ Níbi gbogbo, wọ́n á mú kí ẹbọ rú èéfín, wọ́n á sì mú àwọn ọrẹ wá torí orúkọ mi, bí ẹ̀bùn tó mọ́; torí wọn yóò gbé orúkọ mi ga láàárín àwọn orílẹ̀-èdè,”+ ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́