23 Wọn ò ní fi àwọn òrìṣà ẹ̀gbin* wọn àti àwọn ohun ìríra tí wọ́n ń ṣe àti gbogbo ìṣìnà wọn sọ ara wọn di ẹlẹ́gbin mọ́.+ Èmi yóò gbà wọ́n nínú gbogbo ìwà àìṣòótọ́ wọn tó mú wọn dẹ́ṣẹ̀, èmi yóò sì wẹ̀ wọ́n mọ́. Wọ́n á di èèyàn mi, èmi yóò sì di Ọlọ́run wọn.+
26 “‘“Èmi yóò bá wọn dá májẹ̀mú àlàáfíà;+ májẹ̀mú ayérayé ni màá bá wọn dá. Èmi yóò gbé wọn kalẹ̀, màá sọ wọ́n di púpọ̀,+ màá sì fi ibi mímọ́ mi sí àárín wọn títí láé.
16 Kí ló pa òrìṣà pọ̀ mọ́ tẹ́ńpìlì Ọlọ́run?+ Nítorí àwa jẹ́ tẹ́ńpìlì Ọlọ́run alààyè;+ bí Ọlọ́run ṣe sọ pé: “Èmi yóò máa gbé láàárín wọn,+ èmi yóò sì máa rìn láàárín wọn, èmi yóò jẹ́ Ọlọ́run wọn, wọn yóò sì di èèyàn mi.”+