-
Léfítíkù 8:18-21Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
18 Ó mú àgbò tó fẹ́ fi rú ẹbọ sísun náà wá sí tòsí, Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ sì gbé ọwọ́ lé orí àgbò náà.+ 19 Lẹ́yìn náà, Mósè pa á, ó sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sí gbogbo ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ. 20 Ó gé àgbò náà sí wẹ́wẹ́, Mósè sì mú kí orí àgbò náà, àwọn ègé rẹ̀ àti ọ̀rá rẹ̀ líle* rú èéfín. 21 Ó fi omi fọ ìfun àti ẹsẹ̀ rẹ̀, Mósè sì mú kí odindi àgbò náà rú èéfín lórí pẹpẹ. Ẹbọ sísun tó ní òórùn dídùn* ni. Ọrẹ àfinásun sí Jèhófà ló jẹ́, bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ fún Mósè.
-
-
Ìsíkíẹ́lì 45:19Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
19 Àlùfáà yóò mú lára ẹ̀jẹ̀ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, yóò sì fi sára férémù ilẹ̀kùn tẹ́ńpìlì náà,+ sí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ìgbásẹ̀ tó yí pẹpẹ náà ká àti sára férémù ilẹ̀kùn ẹnubodè àgbàlá inú.
-