2 Kí o tún mú àwọn arákùnrin rẹ tí wọ́n jẹ́ ara ẹ̀yà Léfì sún mọ́ tòsí, ẹ̀yà baba ńlá rẹ, kí wọ́n lè dara pọ̀ mọ́ ọ, kí wọn sì máa bá ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ ṣiṣẹ́+ níwájú àgọ́ Ẹ̀rí.+
4 Kí wọ́n dara pọ̀ mọ́ ọ, kí wọ́n sì máa ṣe ojúṣe wọn tó jẹ mọ́ àgọ́ ìpàdé àti gbogbo iṣẹ́ àgọ́ náà, ẹnikẹ́ni tí kò lẹ́tọ̀ọ́* sí i kò sì gbọ́dọ̀ sún mọ́ yín.+