-
Nọ́ńbà 15:20Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
20 Kí ẹ mú ọrẹ wá látinú àkọ́so+ ọkà yín tí ẹ kò lọ̀ kúnná, kí ẹ fi ṣe àwọn búrẹ́dì tó rí bí òrùka. Bí ọrẹ ibi ìpakà ni kí ẹ ṣe mú un wá.
-
-
Nehemáyà 10:35-37Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
35 A ó tún máa mú àkọ́so èso ilẹ̀ wa àti àkọ́so èso oríṣiríṣi igi wá lọ́dọọdún sí ilé Jèhófà+ 36 àti àkọ́bí àwọn ọmọkùnrin wa àti ti ẹran ọ̀sìn wa+ pẹ̀lú àkọ́bí ọ̀wọ́ ẹran wa àti ti agbo ẹran wa bó ṣe wà lákọsílẹ̀ nínú Òfin. A ó mú wọn wá sí ilé Ọlọ́run wa, sọ́dọ̀ àwọn àlùfáà tó ń ṣiṣẹ́ nínú ilé Ọlọ́run wa.+ 37 Bákan náà, a ó máa mú àkọ́so ọkà tí a kò lọ̀ kúnná+ wá àti àwọn ọrẹ pẹ̀lú èso oríṣiríṣi igi+ àti wáìnì tuntun pẹ̀lú òróró,+ a ó sì kó wọn wá fún àwọn àlùfáà ní àwọn yàrá tí wọ́n ń kó nǹkan pa mọ́ sí* ní ilé Ọlọ́run wa,+ a ó sì kó ìdá mẹ́wàá irè oko ilẹ̀ wa fún àwọn ọmọ Léfì,+ torí àwọn ni wọ́n ń gba ìdá mẹ́wàá ní gbogbo ìlú tí a ti ń ṣiṣẹ́ àgbẹ̀.
-