13 “‘Tó bá wá ṣẹlẹ̀ pé gbogbo àpéjọ Ísírẹ́lì dẹ́ṣẹ̀ láìmọ̀ọ́mọ̀,+ tí wọ́n sì jẹ̀bi, àmọ́ tí gbogbo ìjọ ò mọ̀ pé àwọn ti ṣe ohun tí Jèhófà pa láṣẹ pé kí wọ́n má ṣe,+ 14 tí wọ́n bá wá mọ̀ pé wọ́n dẹ́ṣẹ̀, kí ìjọ mú akọ ọmọ màlúù kan wá láti fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, kí wọ́n sì mú un wá síwájú àgọ́ ìpàdé.