12 Nítorí náà, ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí: ‘Wò ó, màá fa àjálù bá Jerúsálẹ́mù+ àti Júdà, tó jẹ́ pé bí ẹnikẹ́ni bá gbọ́ nípa rẹ̀, etí rẹ̀ méjèèjì á hó yee.+
12 Ó ti ṣe ohun tó sọ lòdì sí àwa+ àti àwọn alákòóso wa tí wọ́n jọba lé wa lórí,* torí ó mú kí àjálù ńlá ṣẹlẹ̀ sí wa; ohunkóhun ò ṣẹlẹ̀ rí lábẹ́ gbogbo ọ̀run bí èyí tó ṣẹlẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù.+