11 “‘Torí náà, bí mo ti wà láàyè,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, ‘torí pé ẹ fi àwọn òrìṣà ẹ̀gbin yín àti àwọn ohun ìríra tí ẹ̀ ń ṣe sọ ibi mímọ́ mi di aláìmọ́,+ èmi náà yóò kọ̀ yín;* mi ò ní ṣàánú yín, mi ò sì ní yọ́nú sí yín.+
9 Mi ò ní ṣàánú yín; mi ò sì ní yọ́nú sí yín.+ Màá fi ìwà yín san yín lẹ́san, ẹ ó sì jìyà gbogbo ohun ìríra tí ẹ ṣe. Ẹ ó sì wá mọ̀ pé èmi Jèhófà ló ń fìyà jẹ yín.+