-
Ẹ́kísódù 32:26, 27Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
26 Lẹ́yìn náà, Mósè dúró ní ẹnubodè àgọ́ náà, ó sì sọ pé: “Ta ló fara mọ́ Jèhófà? Kó máa bọ̀ lọ́dọ̀ mi!”+ Gbogbo àwọn ọmọ Léfì sì kóra jọ sọ́dọ̀ rẹ̀. 27 Ó wá sọ fún wọn pé: “Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí, ‘Kí kálukú yín sán idà rẹ̀ mọ́ ẹ̀gbẹ́, kí ẹ sì lọ káàkiri àgọ́ náà láti ẹnubodè sí ẹnubodè, kí kálukú pa arákùnrin rẹ̀, aládùúgbò rẹ̀ àti ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́.’”+
-