13 Èlíṣà sọ fún ọba Ísírẹ́lì pé: “Kí ló pa èmi àti ìwọ pọ̀?*+ Lọ bá àwọn wòlíì bàbá rẹ àti àwọn wòlíì ìyá rẹ.”+ Àmọ́ ọba Ísírẹ́lì sọ fún un pé: “Rárá, torí Jèhófà ló pe àwọn ọba mẹ́ta yìí kó lè fi wọ́n lé Móábù lọ́wọ́.”
11 Torí náà, ohun tí Jèhófà sọ nìyí, ‘Wò ó, màá mú àjálù+ tí wọn kò ní lè bọ́ nínú rẹ̀ wá bá wọn. Nígbà tí wọ́n bá ké pè mí fún ìrànlọ́wọ́, mi ò ní fetí sí wọn.+