Diutarónómì 30:15 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 15 “Wò ó, mo fi ìyè àti ire, ikú àti ibi+ sí iwájú rẹ lónìí. Òwe 8:36 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 36 Àmọ́ ẹni tó bá pa mí tì, ara* rẹ̀ ló ń ṣe,Àwọn tó sì kórìíra mi fẹ́ràn ikú.”+ Ìṣe 13:46 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 46 Ni Pọ́ọ̀lù àti Bánábà bá fi ìgboyà sọ fún wọn pé: “Ó pọn dandan pé ẹ̀yin ni kí a kọ́kọ́ sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún.+ Nígbà tí ẹ sì ti kọ̀ ọ́, tí ẹ ò ka ara yín sí ẹni tó yẹ fún ìyè àìnípẹ̀kun, torí náà, a yíjú sí àwọn orílẹ̀-èdè.+
46 Ni Pọ́ọ̀lù àti Bánábà bá fi ìgboyà sọ fún wọn pé: “Ó pọn dandan pé ẹ̀yin ni kí a kọ́kọ́ sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún.+ Nígbà tí ẹ sì ti kọ̀ ọ́, tí ẹ ò ka ara yín sí ẹni tó yẹ fún ìyè àìnípẹ̀kun, torí náà, a yíjú sí àwọn orílẹ̀-èdè.+