28 Kò sí ẹni tó lágídí tó wọn láyé,+
Wọ́n ń rìn káàkiri bí abanijẹ́.+
Wọ́n dà bíi bàbà àti irin;
Ìwà ìbàjẹ́ kún ọwọ́ gbogbo wọn.
29 Ẹwìrì wọn ti jóná.
Òjé ló ń jáde látinú iná wọn.
Ẹni tó ń yọ́ nǹkan mọ́ kàn ń ṣiṣẹ́ lásán ni,+
Àwọn tí kò dára kò sì yọ́ kúrò.+
30 Ó dájú pé fàdákà tí a kọ̀ ni àwọn èèyàn máa pè wọ́n,
Nítorí Jèhófà ti kọ̀ wọ́n.”+