4 Wọ́n á run ògiri Tírè, wọ́n á wó àwọn ilé gogoro rẹ̀,+ màá ha iyẹ̀pẹ̀ rẹ̀ kúrò, màá sì sọ ọ́ di àpáta lásán tó ń dán. 5 Yóò di ibi tí wọ́n ń sá àwọ̀n sí láàárín òkun.’+
“‘Torí èmi fúnra mi ti sọ̀rọ̀,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, ‘àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì kó o ní ẹrù.