ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Àìsáyà 47:12, 13
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 12 Máa fi èèdì di àwọn èèyàn lọ, kí o sì máa ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ àjẹ́ rẹ,+

      Èyí tí o ti ń ṣe kára látìgbà ọ̀dọ́ rẹ.

      Bóyá wàá lè jàǹfààní;

      Bóyá wàá lè mú kí ẹ̀rù ba àwọn èèyàn.

      13 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn agbani-nímọ̀ràn rẹ ti tán ọ lókun.

      Kí wọ́n dìde báyìí, kí wọ́n sì gbà ọ́ là,

      Àwọn tó ń jọ́sìn ọ̀run,* tí wọ́n ń wo ìràwọ̀,+

      Àwọn tó ń fúnni ní ìmọ̀ nígbà òṣùpá tuntun,

      Nípa àwọn ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí ọ.

  • Dáníẹ́lì 2:10, 11
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 10 Àwọn ará Kálídíà dá ọba lóhùn, wọ́n ní: “Kò sí ẹnì kankan ní ayé* tó lè ṣe ohun tí ọba ń béèrè, torí kò sí ọba ńlá tàbí gómìnà tó tíì béèrè irú rẹ̀ rí lọ́wọ́ àlùfáà onídán, pidánpidán tàbí ará Kálídíà kankan. 11 Àmọ́ ohun tí ọba ń béèrè ṣòro gan-an, kò sí ẹnì kankan tó lè sọ ọ́ fún ọba àfi àwọn ọlọ́run, tí kì í gbé láàárín àwọn ẹni kíkú.”*

  • Dáníẹ́lì 5:8
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 8 Gbogbo àwọn amòye ọba wá wọlé, àmọ́ wọn ò lè ka ọ̀rọ̀ náà, wọn ò sì lè sọ ohun tó túmọ̀ sí fún ọba.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́