-
Jeremáyà 27:6, 7Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
6 Ní báyìí, mo ti fi gbogbo ilẹ̀ yìí lé ọwọ́ ìránṣẹ́ mi, Nebukadinésárì+ ọba Bábílónì, kódà mo ti fún un ní àwọn ẹran inú igbó kí wọ́n lè máa sìn ín. 7 Gbogbo orílẹ̀-èdè yóò máa sin òun àti ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú ọmọ ọmọ rẹ̀, títí di àkókò tí ìjọba rẹ̀ máa dópin,+ tí ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè àti àwọn ọba ńlá yóò sì sọ ọ́ di ẹrú wọn.’+
-
-
Jeremáyà 50:1, 2Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
50 Ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ nípa Bábílónì,+ nípa ilẹ̀ àwọn ará Kálídíà, nípasẹ̀ wòlíì Jeremáyà nìyí:
2 “Ẹ sọ ọ́ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè kí ẹ sì kéde rẹ̀.
Ẹ gbé àmì kan dúró,* ẹ sì kéde rẹ̀.
Ẹ má fi nǹkan kan pa mọ́!
Ẹ sọ pé, ‘Wọ́n ti gba Bábílónì.+
Ìtìjú ti bá Bélì.+
Méródákì wà nínú ìbẹ̀rù.
Ìtìjú ti bá àwọn ère rẹ̀.
Àwọn òrìṣà ẹ̀gbin rẹ̀* wà nínú ìbẹ̀rù.’
-