8 Òbúkọ náà wá gbé ara rẹ̀ ga kọjá ààlà, àmọ́ gbàrà tó di alágbára, ìwo ńlá náà ṣẹ́; ìwo mẹ́rin tó hàn kedere sì jáde dípò ìwo kan ṣoṣo náà, wọ́n dojú kọ atẹ́gùn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ọ̀run.+
4 Àmọ́ tó bá ti dìde, ìjọba rẹ̀ máa fọ́, ó sì máa pín sí ọ̀nà atẹ́gùn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ọ̀run,+ àmọ́ kì í ṣe fún àwọn àtọmọdọ́mọ rẹ̀,* àkóso wọn ò sì ní lágbára bíi tiẹ̀; torí a máa fa ìjọba rẹ̀ tu, ó sì máa di ti àwọn míì yàtọ̀ sí àwọn yìí.