15 Wọ́n ń pa àwọn ìlànà rẹ̀ tì àti májẹ̀mú+ rẹ̀ tó bá àwọn baba ńlá wọn dá àti àwọn ìránnilétí rẹ̀ tó fi kìlọ̀ fún wọn,+ wọ́n ń sin àwọn òrìṣà asán,+ àwọn fúnra wọn sì di asán,+ torí wọ́n ń fara wé àwọn orílẹ̀-èdè tó yí wọn ká tí Jèhófà pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n má ṣe fara wé.+
26 “Àmọ́, wọ́n ya aláìgbọràn, wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí ọ,+ wọ́n sì kẹ̀yìn sí Òfin rẹ.* Wọ́n pa àwọn wòlíì rẹ tó kìlọ̀ fún wọn láti mú wọn pa dà sọ́dọ̀ rẹ, wọ́n sì hu ìwà àìlọ́wọ̀ tó bùáyà.+