-
1 Àwọn Ọba 12:32, 33Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
32 Jèróbóámù tún dá àjọyọ̀ kan sílẹ̀ ní oṣù kẹjọ, ní ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún oṣù náà, bí àjọyọ̀ tó wà ní Júdà.+ Ó rú ẹbọ sí àwọn ère ọmọ màlúù tó ṣe sórí àwọn pẹpẹ tó ṣe ní Bẹ́tẹ́lì,+ ó sì yan àwọn àlùfáà ní Bẹ́tẹ́lì fún àwọn ibi gíga tó ṣe. 33 Ó bẹ̀rẹ̀ sí í mú àwọn ọrẹ wá sórí pẹpẹ tó ṣe ní Bẹ́tẹ́lì ní ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún ní oṣù kẹjọ, ní oṣù tí òun fúnra rẹ̀ yàn; ó dá àjọyọ̀ kan sílẹ̀ fún àwọn èèyàn Ísírẹ́lì, ó sì lọ sórí pẹpẹ láti mú ọrẹ àti ẹbọ rú èéfín.
-
-
Hósíà 13:1, 2Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
13 “Nígbà tí Éfúrémù sọ̀rọ̀, ẹ̀rù ba àwọn èèyàn;
Torí pé ẹni ńlá ni ní Ísírẹ́lì.+
Àmọ́, ó jẹ̀bi nítorí ó sin Báálì,+ ó sì kú.
2 Ní báyìí, wọ́n dá ẹ̀ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀
Wọ́n sì fi fàdákà+ wọn ṣe ère onírin;*
Wọ́n ṣe àwọn òrìṣà lọ́nà tó já fáfá, gbogbo rẹ̀ sì jẹ́ ohun tí oníṣẹ́ ọnà ṣe.
Wọ́n sọ nípa wọn pé, ‘Kí àwọn tó wá rúbọ fi ẹnu ko àwọn ọmọ màlúù lẹ́nu.’+
-