9 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń ṣe àwọn nǹkan tí Jèhófà Ọlọ́run wọn sọ pé kò tọ́. Wọ́n ń kọ́ àwọn ibi gíga ní gbogbo àwọn ìlú wọn,+ láti ilé ìṣọ́ títí dé ìlú olódi.*10 Wọ́n ń gbé àwọn ọwọ̀n òrìṣà àti àwọn òpó òrìṣà*+ kalẹ̀ fún ara wọn lórí gbogbo òkè àti lábẹ́ gbogbo igi tó gbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀;+