23 Ní ọdún kẹẹ̀ẹ́dógún Amasááyà ọmọ Jèhóáṣì ọba Júdà, Jèróbóámù+ ọmọ Jèhóáṣì ọba Ísírẹ́lì di ọba ní Samáríà, ọdún mọ́kànlélógójì (41) ló sì fi ṣàkóso. 24 Ó ń ṣe ohun tó burú ní ojú Jèhófà. Kò jáwọ́ nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí Jèróbóámù ọmọ Nébátì mú kí Ísírẹ́lì dá.+
1Ọ̀rọ̀ Émọ́sì,* ọ̀kan lára àwọn tó ń sin àgùntàn láti Tékóà,+ èyí tó gbọ́ nínú ìran nípa Ísírẹ́lì nígbà ayé Ùsáyà+ ọba Júdà àti nígbà ayé Jèróbóámù+ ọmọ Jóáṣì,+ ọba Ísírẹ́lì, ní ọdún méjì ṣáájú ìmìtìtì ilẹ̀ tó wáyé.+