23 Ní ọdún kẹẹ̀ẹ́dógún Amasááyà ọmọ Jèhóáṣì ọba Júdà, Jèróbóámù+ ọmọ Jèhóáṣì ọba Ísírẹ́lì di ọba ní Samáríà, ọdún mọ́kànlélógójì (41) ló sì fi ṣàkóso. 24 Ó ń ṣe ohun tó burú ní ojú Jèhófà. Kò jáwọ́ nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí Jèróbóámù ọmọ Nébátì mú kí Ísírẹ́lì dá.+
10 Amasááyà àlùfáà Bẹ́tẹ́lì+ ránṣẹ́ sí Jèróbóámù+ ọba Ísírẹ́lì pé: “Émọ́sì ń dìtẹ̀ sí ọ láàárín ilé Ísírẹ́lì.+ Àwọn èèyàn ilẹ̀ náà kò lè rí ara gba gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ̀.+