-
Jeremáyà 26:8, 9Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
8 Nígbà tí Jeremáyà parí gbogbo ohun tí Jèhófà pàṣẹ fún un pé kó sọ fún gbogbo àwọn èèyàn náà, ńṣe ni àwọn àlùfáà àti àwọn wòlíì pẹ̀lú gbogbo àwọn èèyàn náà gbá a mú, wọ́n sì sọ pé: “Ó dájú pé o máa kú. 9 Kí nìdí tí o fi sọ tẹ́lẹ̀ ní orúkọ Jèhófà, pé, ‘Ilé yìí máa dà bíi Ṣílò, ìlú yìí á sì di ahoro tí kò ní sí ẹnì kankan tí á máa gbé ibẹ̀’?” Gbogbo àwọn èèyàn náà sì pé jọ yí Jeremáyà ká ní ilé Jèhófà.
-