15 Torí náà, Sọ́ọ̀lù rán àwọn òjíṣẹ́ náà láti lọ rí Dáfídì, ó sì sọ pé: “Ẹ gbé e wá fún mi lórí ibùsùn rẹ̀, kí n lè pa á.”+ 16 Nígbà tí àwọn òjíṣẹ́ náà wọlé, ère tẹ́ráfímù ló wà lórí ibùsùn náà, àwọ̀n tó ní irun ewúrẹ́ ló sì wà níbi tó yẹ kí orí rẹ̀ wà.