-
2 Àwọn Ọba 17:15, 16Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
15 Wọ́n ń pa àwọn ìlànà rẹ̀ tì àti májẹ̀mú+ rẹ̀ tó bá àwọn baba ńlá wọn dá àti àwọn ìránnilétí rẹ̀ tó fi kìlọ̀ fún wọn,+ wọ́n ń sin àwọn òrìṣà asán,+ àwọn fúnra wọn sì di asán,+ torí wọ́n ń fara wé àwọn orílẹ̀-èdè tó yí wọn ká tí Jèhófà pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n má ṣe fara wé.+
16 Wọ́n ń pa gbogbo àṣẹ Jèhófà Ọlọ́run wọn tì, wọ́n sì ṣe ère onírin* ọmọ màlúù méjì,+ wọ́n ṣe òpó òrìṣà,*+ wọ́n ń forí balẹ̀ fún gbogbo ọmọ ogun ọ̀run,+ wọ́n sì ń sin Báálì.+
-