-
2 Àwọn Ọba 10:29-31Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
29 Àmọ́, Jéhù ò kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ tí Jèróbóámù ọmọ Nébátì mú kí Ísírẹ́lì dá, ìyẹn jíjọ́sìn àwọn ọmọ màlúù wúrà tó wà ní Bẹ́tẹ́lì àti Dánì.+ 30 Torí náà, Jèhófà sọ fún Jéhù pé: “Nítorí pé o ṣe dáadáa, tí o sì ṣe ohun tí ó tọ́ lójú mi, bí o ṣe ṣe gbogbo ohun tó wà lọ́kàn mi sí ilé Áhábù,+ àwọn ọmọ rẹ títí dé ìran kẹrin yóò máa jókòó lórí ìtẹ́ Ísírẹ́lì.”+ 31 Àmọ́ Jéhù ò kíyè sára láti fi gbogbo ọkàn rẹ̀ pa Òfin Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì mọ́.+ Kò kúrò nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí Jèróbóámù mú kí Ísírẹ́lì dá.+
-