3 Nítorí, “wò ó! ọjọ́ ń bọ̀,” ni Jèhófà wí, “tí màá kó àwọn èèyàn mi, Ísírẹ́lì àti Júdà, tó wà lóko ẹrú jọ,”+ ni Jèhófà wí, “màá mú wọn pa dà wá sí ilẹ̀ tí mo fún àwọn baba ńlá wọn, yóò sì pa dà jẹ́ tiwọn.”’”+
25 “Torí náà, ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Èmi yóò dá àwọn èèyàn Jékọ́bù tí wọ́n kó lẹ́rú pa dà,+ màá sì ṣàánú gbogbo ilé Ísírẹ́lì;+ èmi yóò fi ìtara gbèjà orúkọ mímọ́ mi.*+