-
Léfítíkù 26:14-16Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
14 “‘Àmọ́, tí ẹ ò bá fetí sí mi, tí ẹ ò sì pa gbogbo àṣẹ yìí mọ́,+ 15 tí ẹ bá kọ àwọn òfin mi,+ tí ẹ* sì kórìíra àwọn ìdájọ́ mi débi pé ẹ ò pa gbogbo àṣẹ mi mọ́, tí ẹ sì da májẹ̀mú mi,+ 16 èmi, ní tèmi, yóò ṣe nǹkan wọ̀nyí sí yín: màá kó ìdààmú bá yín láti fìyà jẹ yín, màá fi ikọ́ ẹ̀gbẹ àti akọ ibà ṣe yín, yóò mú kí ojú yín di bàìbàì, kí ẹ* sì ṣègbé. Lásán ni ẹ máa fún irúgbìn yín, torí àwọn ọ̀tá yín ni yóò jẹ ẹ́.+
-
-
2 Kíróníkà 36:14Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
14 Gbogbo olórí àwọn àlùfáà àti àwọn èèyàn náà hùwà àìṣòótọ́ tó bùáyà, wọ́n ń ṣe àwọn ohun ìríra tí àwọn orílẹ̀-èdè ń ṣe, wọ́n sì sọ ilé Jèhófà di ẹlẹ́gbin,+ èyí tó ti yà sí mímọ́ ní Jerúsálẹ́mù.
-