31 “Jèhófà wá sọ fún mi pé, ‘Wò ó, mo ti ń fi Síhónì àti ilẹ̀ rẹ̀ lé ọ lọ́wọ́. Bẹ̀rẹ̀ sí í gba ilẹ̀ rẹ̀.’+ 32 Nígbà tí Síhónì àti gbogbo èèyàn rẹ̀ jáde wá gbógun jà wá ní Jáhásì,+ 33 Jèhófà Ọlọ́run wa fi í lé wa lọ́wọ́, a sì ṣẹ́gun òun àtàwọn ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo èèyàn rẹ̀.