5 “Torí idà mi máa rin gbingbin ní ọ̀run.+
Ó máa sọ̀ kalẹ̀ sórí Édómù láti ṣèdájọ́,+
Sórí àwọn èèyàn tí màá pa run.
6 Jèhófà ní idà kan; ẹ̀jẹ̀ máa bò ó.
Ọ̀rá+ máa bò ó,
Ẹ̀jẹ̀ àwọn ọmọ àgbò àti ewúrẹ́ máa bò ó,
Ọ̀rá kíndìnrín àwọn àgbò máa bò ó.
Torí pé Jèhófà ní ẹbọ ní Bósírà,
Ó máa pa ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ní ilẹ̀ Édómù.+