-
Àìsáyà 63:1-3Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
63 Ta ló ń bọ̀ láti Édómù+ yìí,
Tó ń bọ̀ láti Bósírà,+ tó wọ aṣọ tí àwọ̀ rẹ̀ ń tàn yòò,*
Tó wọ aṣọ tó dáa gan-an,
Tó ń yan bọ̀ nínú agbára ńlá rẹ̀?
“Èmi ni, Ẹni tó ń fi òdodo sọ̀rọ̀,
Ẹni tó lágbára gan-an láti gbani là.”
2 Kí ló dé tí aṣọ rẹ pọ́n,
Kí ló sì dé tí ẹ̀wù rẹ dà bíi ti ẹni tó ń tẹ àjàrà ní ibi tí wọ́n ti ń fún wáìnì?+
3 “Èmi nìkan ni mo tẹ wáìnì nínú ọpọ́n.
Ìkankan nínú àwọn èèyàn náà ò sí lọ́dọ̀ mi.
Mò ń fi ìbínú tẹ̀ wọ́n ṣáá,
Mo sì ń fi ìrunú tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀.+
Ẹ̀jẹ̀ wọn ta sára ẹ̀wù mi,
Ó sì ti yí gbogbo aṣọ mi.
-
-
Ọbadáyà 8, 9Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
8 Ní ọjọ́ yẹn,” ni Jèhófà wí,
“Èmi yóò pa àwọn ọlọ́gbọ́n run kúrò ní Édómù+
Èmi yóò sì pa òye run ní agbègbè olókè Ísọ̀.
-