-
Diutarónómì 10:12, 13Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
12 “Ní báyìí, ìwọ Ísírẹ́lì, kí ni Jèhófà Ọlọ́run rẹ fẹ́ kí o ṣe?+ Kò ju pé: kí o máa bẹ̀rù Jèhófà Ọlọ́run rẹ,+ kí o máa rìn ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀,+ kí o máa nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, kí o máa fi gbogbo ọkàn rẹ àti gbogbo ara* rẹ sin Jèhófà Ọlọ́run rẹ,+ 13 kí o sì máa pa àwọn òfin àti àṣẹ Jèhófà tí mò ń pa láṣẹ fún ọ lónìí mọ́ fún àǹfààní ara rẹ.+
-