Sáàmù 46:1 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 46 Ọlọ́run ni ibi ààbò wa àti okun wa,+Ìrànlọ́wọ́ tó wà lárọ̀ọ́wọ́tó ní àkókò wàhálà.+ Sáàmù 91:2 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 2 Màá sọ fún Jèhófà pé: “Ìwọ ni ibi ààbò mi àti odi ààbò mi,+Ọlọ́run mi tí mo gbẹ́kẹ̀ lé.”+ Òwe 18:10 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 10 Orúkọ Jèhófà jẹ́ ilé gogoro tó lágbára.+ Olódodo sá wọ inú rẹ̀, ó sì rí ààbò.*+ Àìsáyà 25:4 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 4 Torí o ti di ibi ààbò fún ẹni rírẹlẹ̀,Ibi ààbò fún aláìní nínú ìdààmú rẹ̀,+Ibi ààbò kúrò lọ́wọ́ ìjì òjò,Àti ibòji kúrò lọ́wọ́ ooru.+ Nígbà tí atẹ́gùn líle àwọn ìkà bá dà bí ìjì òjò tó kọ lu ògiri,
4 Torí o ti di ibi ààbò fún ẹni rírẹlẹ̀,Ibi ààbò fún aláìní nínú ìdààmú rẹ̀,+Ibi ààbò kúrò lọ́wọ́ ìjì òjò,Àti ibòji kúrò lọ́wọ́ ooru.+ Nígbà tí atẹ́gùn líle àwọn ìkà bá dà bí ìjì òjò tó kọ lu ògiri,