2 “Ohun tí Jèhófà sọ nìyí,
‘“Nítorí ìdìtẹ̀ mẹ́ta Móábù+ àti nítorí mẹ́rin, mi ò ní yí ọwọ́ mi pa dà,
Nítorí pé ó jó egungun ọba Édómù láti fi ṣe ẹfun.
2 Torí náà, màá rán iná sí Móábù,
Á sì jó àwọn ilé gogoro tó láàbò ti Kíríọ́tì+ run;
Móábù á kú sínú ariwo,
Nígbà tí ariwo bá sọ nítorí ogun, tí ìró ìwo sì dún.+