ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jeremáyà 30:10
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 10 “Ní tìrẹ, ìwọ Jékọ́bù ìránṣẹ́ mi, má fòyà,” ni Jèhófà wí,

      “Má sì jẹ́ kí ẹ̀rù bà ọ́, ìwọ Ísírẹ́lì.+

      Nítorí màá gbà ọ́ láti ibi tó jìnnà réré

      Àti àwọn ọmọ rẹ láti oko ẹrú tí wọ́n wà.+

      Jékọ́bù á pa dà, ara rẹ̀ á balẹ̀, kò ní rí ìyọlẹ́nu,

      Ẹnì kankan ò sì ní dẹ́rù bà wọ́n.”+

  • Ìsíkíẹ́lì 34:28
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 28 Àwọn orílẹ̀-èdè ò ní dọdẹ wọn mọ́, àwọn ẹran inú igbó ò ní pa wọ́n jẹ, ààbò yóò sì wà lórí wọn, ẹnì kankan ò sì ní dẹ́rù bà wọ́n.+

  • Ìsíkíẹ́lì 39:25, 26
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 25 “Torí náà, ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Èmi yóò dá àwọn èèyàn Jékọ́bù tí wọ́n kó lẹ́rú pa dà,+ màá sì ṣàánú gbogbo ilé Ísírẹ́lì;+ èmi yóò fi ìtara gbèjà orúkọ mímọ́ mi.*+ 26 Lẹ́yìn tí wọ́n bá sì ti dójú tì wọ́n torí gbogbo ìwà àìṣòótọ́ tí wọ́n hù sí mi,+ wọn yóò máa gbé lórí ilẹ̀ wọn láìséwu, ẹnì kankan ò sì ní dẹ́rù bà wọ́n.+

  • Hósíà 2:18
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 18 Ní ọjọ́ yẹn, màá bá àwọn ẹran inú igbó dá májẹ̀mú nítorí wọn,+

      Màá sì bá àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run àti ohun tó ń rákò lórí ilẹ̀ dá májẹ̀mú;+

      Màá mú ọfà* àti idà àti ogun kúrò ní ilẹ̀ náà,+

      Màá sì jẹ́ kí wọ́n dùbúlẹ̀* ní ààbò.+

  • Míkà 4:4
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  4 Kálukú wọn máa jókòó* lábẹ́ àjàrà rẹ̀ àti lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀,+

      Ẹnì kankan ò sì ní dẹ́rù bà wọ́n,+

      Torí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun ló fi ẹnu ara rẹ̀ sọ ọ́.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́