37 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wá kúrò ní Rámésésì,+ wọ́n sì forí lé Súkótù,+ wọ́n tó nǹkan bí ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ (600,000) ọkùnrin tó ń fẹsẹ̀ rìn, yàtọ̀ sí àwọn ọmọdé.+ 38 Oríṣiríṣi èèyàn tó pọ̀ rẹpẹtẹ+ ló tún bá wọn lọ, pẹ̀lú àwọn agbo ẹran àti ọ̀wọ́ ẹran, ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ẹran ọ̀sìn.