ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jẹ́nẹ́sísì 12:1, 2
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 12 Jèhófà sì sọ fún Ábúrámù pé: “Kúrò ní ilẹ̀ rẹ, kí o kúrò lọ́dọ̀ àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ àti ilé bàbá rẹ, kí o lọ sí ilẹ̀ tí màá fi hàn ọ́.+ 2 Màá mú kí o di orílẹ̀-èdè ńlá, màá sì bù kún ọ. Màá mú kí orúkọ rẹ di ńlá, ó sì máa jẹ́ ìbùkún.+

  • Jẹ́nẹ́sísì 15:1
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 15 Lẹ́yìn èyí, Jèhófà sọ fún Ábúrámù nínú ìran pé: “Ábúrámù, má bẹ̀rù.+ Apata ni mo jẹ́ fún ọ.+ Èrè rẹ yóò pọ̀ gan-an.”+

  • Jẹ́nẹ́sísì 15:5
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 5 Ó wá mú un wá sí ìta, ó sì sọ pé: “Jọ̀ọ́, gbójú sókè wo ọ̀run, kí o sì ka àwọn ìràwọ̀, tí o bá lè kà á.” Ó sì sọ fún un pé: “Bí ọmọ* rẹ á ṣe pọ̀ nìyẹn.”+

  • Jẹ́nẹ́sísì 46:2, 3
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 2 Lẹ́yìn náà, Ọlọ́run bá Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀ lójú ìran ní òru, ó ní: “Jékọ́bù, Jékọ́bù!” Ó dáhùn pé: “Èmi nìyí!” 3 Ó sọ pé: “Èmi ni Ọlọ́run tòótọ́, Ọlọ́run bàbá+ rẹ. Má bẹ̀rù láti lọ sí Íjíbítì, torí ibẹ̀ ni màá ti sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè ńlá.+

  • Ẹ́kísódù 1:7
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 7 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì* ń bímọ, wọ́n sì ń pọ̀ sí i, wọ́n ń bí sí i, wọ́n sì túbọ̀ ń lágbára gidigidi, débi pé wọ́n kún ilẹ̀ náà.+

  • Nọ́ńbà 2:32
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 32 Èyí ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí agbo ilé bàbá wọn; gbogbo àwọn tó wà nínú àwọn ibùdó tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ láti dara pọ̀ mọ́ àwọn ọmọ ogun jẹ́ ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ ó lé ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ààbọ̀ àti àádọ́ta (603,550).+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́