17 “Bó ṣe ku díẹ̀ kí ìlérí tí Ọlọ́run ṣe fún Ábúráhámù ṣẹ, àwọn èèyàn náà gbilẹ̀, wọ́n sì di púpọ̀ ní Íjíbítì, 18 títí ọba míì fi jẹ ní Íjíbítì, ẹni tí kò mọ Jósẹ́fù.+ 19 Ẹni yìí lo ọgbọ́n àrékérekè fún àwọn èèyàn wa, ó sì fipá mú àwọn bàbá láti pa àwọn ọmọ wọn jòjòló tì, kí wọ́n má bàa wà láàyè.+