-
Nehemáyà 8:7, 8Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
7 Jéṣúà, Bánì, Ṣerebáyà,+ Jámínì, Ákúbù, Ṣábétáì, Hodáyà, Maaseáyà, Kélítà, Asaráyà, Jósábádì,+ Hánánì àti Pẹláyà, tí wọ́n jẹ́ ọmọ Léfì, ń ṣàlàyé Òfin náà fún àwọn èèyàn náà,+ orí ìdúró sì ni àwọn èèyàn náà wà. 8 Wọ́n ń ka ìwé náà sókè nìṣó látinú Òfin Ọlọ́run tòótọ́, wọ́n ń ṣàlàyé rẹ̀ lọ́nà tó ṣe kedere, wọ́n sì ń túmọ̀ rẹ̀; torí náà, wọ́n jẹ́ kí àwọn èèyàn náà lóye ohun tí wọ́n kà.+
-
-
Ìsíkíẹ́lì 44:23, 24Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
23 “‘Kí wọ́n fún àwọn èèyàn mi ní ìtọ́ni nípa ìyàtọ̀ tó wà láàárín ohun tó mọ́ àti ohun yẹpẹrẹ; wọ́n á sì kọ́ wọn ní ìyàtọ̀ tó wà láàárín ohun tí kò mọ́ àti ohun tó mọ́.+ 24 Tí ẹjọ́ kan bá wáyé, àwọn ni kí wọ́n ṣe adájọ́;+ ẹjọ́ tí wọ́n bá dá gbọ́dọ̀ bá àwọn ìdájọ́ mi mu.+ Kí wọ́n máa tẹ̀ lé àwọn òfin àti ìlànà mi tó wà fún gbogbo àwọn àjọ̀dún mi,+ kí wọ́n sì máa sọ àwọn sábáàtì mi di mímọ́.
-