13 Kò sí àdánwò kankan tó ti bá yín àfi èyí tó máa ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn èèyàn.+ Àmọ́ Ọlọ́run jẹ́ olóòótọ́, kò ní jẹ́ kí a dán yín wò kọjá ohun tí ẹ lè mú mọ́ra,+ ṣùgbọ́n nínú àdánwò náà, yóò ṣe ọ̀nà àbáyọ kí ẹ lè fara dà á.+
10 Torí o pa ọ̀rọ̀ nípa ìfaradà mi mọ́,*+ màá pa ìwọ náà mọ́ nígbà wákàtí ìdánwò,+ èyí tó máa dé bá gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé, láti dán àwọn tó ń gbé ayé wò.