-
Máàkù 2:18-20Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
18 Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jòhánù àti àwọn Farisí máa ń gbààwẹ̀. Torí náà, wọ́n wá, wọ́n sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Kí ló dé tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jòhánù àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn àwọn Farisí máa ń gbààwẹ̀ àmọ́ tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ kì í gbààwẹ̀?”+ 19 Jésù sọ fún wọn pé: “Tí ọkọ ìyàwó+ bá ṣì wà lọ́dọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ ọkọ ìyàwó, kò sí ohun tó máa mú kí wọ́n gbààwẹ̀, àbí ó wà? Tí ọkọ ìyàwó bá ṣì wà lọ́dọ̀ wọn, wọn ò lè gbààwẹ̀. 20 Àmọ́ ọjọ́ ń bọ̀, tí a máa mú ọkọ ìyàwó kúrò lọ́dọ̀ wọn,+ wọ́n máa wá gbààwẹ̀ lọ́jọ́ yẹn.
-
-
Lúùkù 5:33-35Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
33 Wọ́n sọ fún un pé: “Léraléra ni àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jòhánù máa ń gbààwẹ̀, tí wọ́n sì ń rawọ́ ẹ̀bẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ọmọ ẹ̀yìn àwọn Farisí, àmọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ ń jẹ, wọ́n sì ń mu.”+ 34 Jésù sọ fún wọn pé: “Ẹ ò lè mú kí àwọn ọ̀rẹ́ ọkọ ìyàwó gbààwẹ̀ tí ọkọ ìyàwó bá ṣì wà lọ́dọ̀ wọn, àbí ẹ lè ṣe bẹ́ẹ̀? 35 Àmọ́ ọjọ́ ń bọ̀, tí a máa mú ọkọ ìyàwó+ kúrò lọ́dọ̀ wọn ní tòótọ́; wọ́n máa wá gbààwẹ̀ láwọn ọjọ́ yẹn.”+
-