8 “Mò ń sọ fún yín pé, gbogbo ẹni tó bá fi hàn pé òun mọ̀ mí níwájú àwọn èèyàn,+ Ọmọ èèyàn náà máa fi hàn pé òun mọ̀ ọ́n níwájú àwọn áńgẹ́lì Ọlọ́run.+9 Àmọ́ ẹnikẹ́ni tó bá sẹ́ mi níwájú àwọn èèyàn, a máa sẹ́ ẹ níwájú àwọn áńgẹ́lì Ọlọ́run.+
5 Torí náà, ẹni tó bá ṣẹ́gun+ máa wọ aṣọ funfun,+ mi ò ní yọ orúkọ rẹ̀ kúrò* nínú ìwé ìyè,+ màá sì fi hàn pé mo mọ orúkọ rẹ̀ níwájú Baba mi àti níwájú àwọn áńgẹ́lì rẹ̀.+