45 Ẹni rere máa ń mú ohun rere jáde látinú ìṣúra rere tó wà nínú ọkàn rẹ̀, àmọ́ ẹni burúkú máa ń mú ohun burúkú jáde látinú ìṣúra burúkú rẹ̀; torí lára ọ̀pọ̀ nǹkan tó wà nínú ọkàn ni ẹnu rẹ̀ ń sọ.+
6 Bákan náà, ahọ́n jẹ́ iná.+ Ahọ́n dúró fún ayé àìṣòdodo lára àwọn ẹ̀yà ara wa, torí ó máa ń sọ gbogbo ara di aláìmọ́,+ ó sì máa ń dáná sí gbogbo ìgbésí ayé* ẹ̀dá, iná Gẹ̀hẹ́nà* á sì sun òun náà.